-
Ẹ́kísódù 16:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Nígbà tí ìrì náà gbẹ, ohun kan wà lórí ilẹ̀ ní aginjù náà tó rí wínníwínní.+ Ó rí bíi yìnyín tó rọ̀ sórí ilẹ̀.
-
-
Ẹ́kísódù 16:31, 32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Ilé Ísírẹ́lì pe oúnjẹ náà ní “mánà.”*+ Ó funfun bí irúgbìn kọriáńdà, ó sì dùn bí àkàrà olóyin pẹlẹbẹ. 32 Mósè sì sọ pé: “Àṣẹ tí Jèhófà pa nìyí, ‘Ẹ kó oúnjẹ náà, kó kún òṣùwọ̀n ómérì kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ìran yín,+ kí wọ́n lè rí oúnjẹ tí mo fún yín ní aginjù nígbà tí mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.’”
-