13 Mósè wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù.+ Ẹ dúró gbọn-in, kí ẹ sì rí bí Jèhófà ṣe máa gbà yín là lónìí.+ Torí àwọn ará Íjíbítì tí ẹ rí lónìí yìí, ẹ ò ní rí wọn mọ́ láé.+
28 Omi náà rọ́ pa dà, ó sì bo àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn agẹṣin àti gbogbo ọmọ ogun Fáráò tó lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọnú òkun.+ Kò sí ìkankan nínú wọn tó yè é.+