ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 14:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Àmọ́ ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn èèyàn ilẹ̀ náà,+ torí a máa jẹ wọ́n run.* Ààbò wọn ti kúrò lórí wọn, Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa.+ Ẹ má bẹ̀rù wọn.”

  • Diutarónómì 20:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Kó sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ọ̀tá yín lẹ fẹ́ lọ bá jagun. Ẹ má ṣojo. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà, ẹ má ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín nítorí wọn,

  • 2 Kíróníkà 20:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ó sọ pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, gbogbo Júdà àti ẹ̀yin tó ń gbé Jerúsálẹ́mù àti Ọba Jèhóṣáfátì! Ohun tí Jèhófà sọ fún yín nìyí, ‘Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn yìí, torí ìjà náà kì í ṣe tiyín, ti Ọlọ́run ni.+

  • 2 Kíróníkà 20:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Kò ní sídìí fún yín láti ja ogun yìí. Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́,+ kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà lórí yín.*+ Ìwọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù, ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà.+ Ní ọ̀la, ẹ jáde sí wọn, Jèhófà á sì wà pẹ̀lú yín.’”+

  • Sáàmù 27:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi+ àti ìgbàlà mi.

      Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?+

      Jèhófà ni odi ààbò ayé mi.+

      Ta ni èmi yóò fòyà?

  • Sáàmù 46:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa,+

      Ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.+

  • Àìsáyà 41:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+

      Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+

      Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+

      Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́