-
Àwọn Onídàájọ́ 10:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn Báálì,+ àwọn ère Áṣítórétì, àwọn ọlọ́run Árámù,* àwọn ọlọ́run Sídónì, àwọn ọlọ́run Móábù,+ àwọn ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì+ àti àwọn ọlọ́run àwọn Filísínì.+ Wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀, wọn ò sì sìn ín. 7 Jèhófà wá bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n lé àwọn Filísínì àtàwọn ọmọ Ámónì lọ́wọ́.+ 8 Wọ́n ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n gidigidi ní ọdún yẹn. Ọdún méjìdínlógún (18) ni wọ́n fi fìyà jẹ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì lápá ibi tó jẹ́ ilẹ̀ àwọn Ámórì tẹ́lẹ̀ ní Gílíádì.
-