-
Àwọn Onídàájọ́ 6:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ torí náà Jèhófà fi wọ́n lé Mídíánì lọ́wọ́ fún ọdún méje.+ 2 Mídíánì wá ń jọba lé Ísírẹ́lì lórí.+ Torí Mídíánì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àwọn ibi tí wọ́n lè sá pa mọ́ sí* nínú àwọn òkè, nínú àwọn ihò àti láwọn ibi tó ṣòroó dé.+ 3 Tí Ísírẹ́lì bá fún irúgbìn, àwọn ọmọ Mídíánì, Ámálékì+ àti àwọn Ará Ìlà Oòrùn+ máa wá gbógun jà wọ́n. 4 Wọ́n á pàgọ́ tì wọ́n, wọ́n á sì run èso ilẹ̀ náà títí dé Gásà, wọn ò ní ṣẹ́ oúnjẹ kankan kù fún Ísírẹ́lì, wọn ò sì ní ṣẹ́ àgùntàn, akọ màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan kù.+ 5 Wọ́n máa ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn àtàwọn àgọ́ wọn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bí eéṣú+ wá, àwọn àtàwọn ràkúnmí wọn kì í níye,+ wọ́n á sì wá sí ilẹ̀ náà láti run ún.
-