14 Màá dà bí ọmọ kìnnìún sí Éfúrémù
Àti bíi kìnnìún alágbára sí ilé Júdà.
Èmi fúnra mi á fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, màá sì lọ;+
Màá gbé wọn lọ, kò sì sí ẹni tó máa gbà wọ́n sílẹ̀.+
15 Màá lọ, màá sì pa dà sí ipò mi títí wọ́n á fi gba ìyà ẹ̀bi wọn,
Nígbà náà, wọ́n á wá ojú rere mi.+
Nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìdààmú, wọ́n á wá mi.”+