9 Ta ló máa mú mi wá sí ìlú tí a dó tì?
Ta ló máa mú mi lọ sí Édómù?+
10 Ìwọ Ọlọ́run tí o ti kọ̀ wá sílẹ̀ náà ni,
Ìwọ Ọlọ́run wa, tí o kò bá àwọn ọmọ ogun wa jáde mọ́.+
11 Ràn wá lọ́wọ́ nínú wàhálà wa,
Nítorí asán ni ìgbàlà látọwọ́ èèyàn.+
12 Ọlọ́run ló máa fún wa lágbára,+
Yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa rẹ́.+