-
2 Sámúẹ́lì 15:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ábúsálómù máa ń dìde láàárọ̀ kùtù, á sì dúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tó lọ sí ẹnubodè ìlú.+ Nígbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ní ẹjọ́ tó ń gbé bọ̀ lọ́dọ̀ ọba,+ Ábúsálómù á pè é, á sì sọ pé: “Ìlú wo lo ti wá?” onítọ̀hún á sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni ìránṣẹ́ rẹ ti wá.” 3 Ábúsálómù á wá sọ fún un pé: “Wò ó, ẹjọ́ rẹ dára, ó sì tọ́, àmọ́ kò sí ẹnì kankan láti ọ̀dọ̀ ọba tó máa fetí sí ọ.”
-
-
Sáàmù 31:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Kí kẹ́kẹ́ pa mọ́ àwọn òpùrọ́ lẹ́nu,+
Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga àti ẹ̀gàn sí àwọn olódodo.
-