10 Torí bí òjò àti yìnyín ṣe ń rọ̀ láti ọ̀run gẹ́lẹ́,
Tí kì í sì í pa dà síbẹ̀, àfi tó bá mú kí ilẹ̀ rin, tó jẹ́ kó méso jáde, kí nǹkan sì hù,
Tó jẹ́ kí ẹni tó fúnrúgbìn ká irúgbìn, tí ẹni tó ń jẹun sì rí oúnjẹ,
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde máa rí.+
Kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ,+
Àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí,+
Ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.