-
Diutarónómì 15:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+ 8 Ṣe ni kí o lawọ́ sí i,+ kí o sì rí i dájú pé o yá a ní* ohunkóhun tó bá nílò tàbí tó ń jẹ ẹ́ níyà.
-
-
Lúùkù 6:34, 35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Bákan náà, tí ẹ bá ń yá* àwọn tí ẹ retí pé wọ́n máa san án pa dà ní nǹkan, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín?+ Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní nǹkan kí wọ́n lè rí ohun kan náà gbà pa dà. 35 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ máa ṣe rere, kí ẹ sì máa yáni ní nǹkan láìretí ohunkóhun pa dà;+ èrè yín máa wá pọ̀, ẹ sì máa jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, torí ó máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.+
-