-
Ìfihàn 7:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn,* tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n,*+ wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun;+ imọ̀ ọ̀pẹ sì wà lọ́wọ́ wọn.+ 10 Wọ́n ń ké jáde pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa tó jókòó sórí ìtẹ́+ àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”+
-