6 Gbogbo àwọn tó ń gbé Íjíbítì á wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,
Torí wọn ò lè ti ilé Ísírẹ́lì lẹ́yìn mọ́, wọn ò yàtọ̀ sí pòròpórò lásán.+
7 Ìwọ fọ́ nígbà tí wọ́n dì ọ́ lọ́wọ́ mú,
O sì mú kí èjìká wọn ya.
Ìwọ ṣẹ́ nígbà tí wọ́n fi ara tì ọ́,
O sì mú kí ẹsẹ̀ wọn di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.”+