-
Jeremáyà 37:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Nígbà náà, àwọn ọmọ ogun Fáráò jáde kúrò ní Íjíbítì,+ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó ti Jerúsálẹ́mù sì gbọ́ ìròyìn nípa wọn. Torí náà, wọ́n ṣígun kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ìgbà náà ni Jèhófà bá wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ máa sọ fún ọba Júdà, tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi láti wádìí nìyí: “Wò ó! Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó ń bọ̀ wá ràn yín lọ́wọ́ yóò ní láti pa dà sí Íjíbítì, ilẹ̀ wọn.+
-