8 Ábíṣáì wá sọ fún Dáfídì pé: “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí.+ Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan péré, mi ò ní ṣe é lẹ́ẹ̀mejì.” 9 Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe é ní jàǹbá, ṣé ẹnì kan lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà,+ kó má sì jẹ̀bi?”+