9 Nígbà tó ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí ọkàn+ àwọn kan lábẹ́ pẹpẹ,+ àwọn tí wọ́n pa torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́.+ 10 Wọ́n ké jáde pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni mímọ́ àti olóòótọ́,+ títí di ìgbà wo lo fi máa dúró kí o tó ṣe ìdájọ́, kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tó ń gbé ayé?”+