-
1 Sámúẹ́lì 1:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Inú Hánà bà jẹ́* gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà,+ ó sì ń sunkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. 11 Ó wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí pé: “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, tí o bá bojú wo ìnira tó dé bá ìránṣẹ́ rẹ, tí o rántí mi, tí o kò gbàgbé ìránṣẹ́ rẹ, tí o sì fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọmọ ọkùnrin,+ ṣe ni màá fi fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, abẹ kò sì ní kan orí rẹ̀.”+
-
-
2 Sámúẹ́lì 16:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Dáfídì bá sọ fún Ábíṣáì àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó, ọmọ tèmi, tó ti ara mi wá ń wọ́nà láti gba ẹ̀mí* mi,+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ẹni tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì!+ Ẹ fi sílẹ̀, kó máa ṣépè fún mi, torí Jèhófà ti sọ fún un pé kó ṣe bẹ́ẹ̀! 12 Bóyá Jèhófà máa rí ìpọ́njú mi,+ tí Jèhófà yóò sì fi ire san án pa dà fún mi dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi lórí lónìí yìí.”+
-
-
Àìsáyà 38:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ìwé* tí Hẹsikáyà ọba Júdà kọ nígbà tó ń ṣàìsàn, tí ara rẹ̀ sì yá.
-