4 Jèhófà sọ fún un pé: “Lọ káàkiri ìlú náà, káàkiri Jerúsálẹ́mù, kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn èèyàn tó ń kẹ́dùn, tí wọ́n sì ń kérora+ torí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe ní ìlú náà.”+
7 Ó gba Lọ́ọ̀tì olódodo là,+ ẹni tó banú jẹ́ gidigidi nítorí ìwà àìnítìjú* àwọn arúfin èèyàn— 8 torí ojoojúmọ́ ni ọkùnrin olódodo yẹn ń mú kí ọkàn* rẹ̀ gbọgbẹ́ nítorí ohun tó rí àti ohun tó gbọ́ tí àwọn arúfin yẹn ń ṣe nígbà tó ń gbé láàárín wọn.