Sáàmù 1:2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Ṣùgbọ́n òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn,+Ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka* òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.+ Sáàmù 40:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí,*+Òfin rẹ sì wà nínú mi lọ́hùn-ún.+ Róòmù 7:22 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 22 Nínú mi lọ́hùn-ún,+ mo nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run gan-an,