Sáàmù 16:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Mo gbé Jèhófà síwájú mi nígbà gbogbo.+ Torí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, mìmì kan ò ní mì mí.*+ Sáàmù 109:31 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 31 Nítorí á dúró ní ọwọ́ ọ̀tún aláìníLáti gbà á lọ́wọ́ àwọn tó ń dá a* lẹ́bi.