Sáàmù 2:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Á sọ pé: “Èmi fúnra mi ti fi ọba mi jẹ+Lórí Síónì,+ òkè mímọ́ mi.” Sáàmù 72:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Yóò ní àwọn ọmọ abẹ́* láti òkun dé òkunÀti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+ Àìsáyà 9:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Torí a ti bí ọmọ kan fún wa,+A ti fún wa ní ọmọkùnrin kan;Àkóso* sì máa wà ní èjìká rẹ̀.+ Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ìfihàn 11:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀.+ Àwọn ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé: “Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa+ àti ti Kristi rẹ̀,+ ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”+
6 Torí a ti bí ọmọ kan fún wa,+A ti fún wa ní ọmọkùnrin kan;Àkóso* sì máa wà ní èjìká rẹ̀.+ Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.
15 Áńgẹ́lì keje fun kàkàkí rẹ̀.+ Àwọn ohùn kan ké jáde ní ọ̀run pé: “Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa+ àti ti Kristi rẹ̀,+ ó sì máa jọba títí láé àti láéláé.”+