ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 23:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 “Màá pààlà fún yín láti Òkun Pupa dé òkun àwọn Filísínì àti láti aginjù dé Odò;*+ torí màá mú kí ọwọ́ yín tẹ àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà, ẹ ó sì lé wọn kúrò níwájú yín.+

  • 1 Àwọn Ọba 4:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Sólómọ́nì ṣàkóso gbogbo àwọn ìjọba láti Odò*+ dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì. Wọ́n ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá, wọ́n sì ń sin Sólómọ́nì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+

  • Sáàmù 2:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  8 Béèrè lọ́wọ́ mi, màá fi àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ogún fún ọ

      Màá sì fi gbogbo ìkángun ayé ṣe ohun ìní fún ọ.+

  • Sáàmù 22:27, 28
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Gbogbo ayé á rántí, wọ́n á sì yíjú sọ́dọ̀ Jèhófà.

      Gbogbo ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè á tẹrí ba níwájú rẹ.+

      28 Nítorí pé ti Jèhófà ni ìjọba;+

      Ó ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè.

  • Dáníẹ́lì 2:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Ìgbà yẹn ni gbogbo irin, amọ̀, bàbà, fàdákà àti wúrà fọ́ túútúú, ó sì dà bí ìyàngbò* láti ibi ìpakà ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, atẹ́gùn sì gbé wọn lọ títí kò fi ṣẹ́ ku nǹkan kan. Àmọ́ òkúta tó kọ lu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.

  • Sekaráyà 9:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Èmi yóò mú kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí wọ́n fi ń jagun kúrò ní Éfúrémù

      Àti ẹṣin kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

      Ọfà tí wọ́n fi ń jagun kò ní sí mọ́.

      Òun yóò sì kéde àlàáfíà fún àwọn orílẹ̀-èdè;+

      Yóò jọba láti òkun dé òkun

      Àti láti Odò* dé àwọn ìkángun ayé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́