9 Lẹ́yìn èyí, wò ó! mo rí ogunlọ́gọ̀ èèyàn,* tí èèyàn kankan kò lè ka iye wọn, wọ́n wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n,*+ wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, wọ́n wọ aṣọ funfun;+ imọ̀ ọ̀pẹ sì wà lọ́wọ́ wọn.+
4 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ Jèhófà,* tí kò ní yin orúkọ rẹ lógo, torí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?+ Torí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa wá jọ́sìn níwájú rẹ,+ torí a ti fi àwọn àṣẹ òdodo rẹ hàn kedere.”