ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 14:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀ sórí òkun;+ Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn líle fẹ́ wá láti ìlà oòrùn ní gbogbo òru yẹn, ó sì bi òkun náà sẹ́yìn. Ó mú kí ìsàlẹ̀ òkun di ilẹ̀ gbígbẹ,+ omi náà sì pínyà.+

  • Nọ́ńbà 11:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Jèhófà wá mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ wá lójijì, ó gbá àwọn ẹyẹ àparò wá láti òkun, ó sì mú kí wọ́n já bọ́ yí ibùdó+ náà ká, nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ibí àti ìrìn àjò ọjọ́ kan lápá ọ̀hún, yí ibùdó náà ká, ìpele wọn sì ga tó nǹkan bí ìgbọ̀nwọ́* méjì sílẹ̀.

  • Jeremáyà 10:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Nígbà tó bá fọhùn,

      Omi ojú ọ̀run á ru gùdù,+

      Á sì mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé.+

      Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò,

      Ó sì ń mú ẹ̀fúùfù wá láti inú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+

  • Jeremáyà 51:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Nígbà tí ó bá fọhùn,

      Omi ojú ọ̀run á ru gùdù,

      Á sì mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé.

      Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò,

      Ó sì ń mú ẹ̀fúùfù wá láti inú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+

  • Jónà 1:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí ìjì kan tó lágbára jà lórí òkun, ìjì náà sì le débi pé ọkọ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ ya.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́