-
Ẹ́sítà 7:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, wọ́n gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi tó ṣe fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọlẹ̀.
-
-
Sáàmù 7:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ó ti wa kòtò, ó sì gbẹ́ ẹ jìn,
Àmọ́ ó já sínú ihò tí òun fúnra rẹ̀ gbẹ́.+
-
-
Sáàmù 9:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti rì sínú kòtò tí wọ́n gbẹ́;
Ẹsẹ̀ wọn ti kó sínú àwọ̀n tí àwọn fúnra wọn dẹ pa mọ́.+
-
-
Sáàmù 57:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Wọ́n ti gbẹ́ kòtò dè mí,
Àmọ́ àwọn fúnra wọn kó sínú rẹ̀.+ (Sélà)
-