47 Jèhófà wà láàyè! Ìyìn ni fún Àpáta mi!+
Kí a gbé Ọlọ́run tó jẹ́ àpáta ìgbàlà mi ga.+
48 Ọlọ́run tòótọ́ ń gbẹ̀san fún mi;+
Ó ń ṣẹ́gun àwọn èèyàn lábẹ́ mi;+
49 Ó ń gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
Ìwọ gbé mi lékè+ àwọn tó ń gbéjà kò mí;
O gbà mí lọ́wọ́ oníwà ipá.+