-
Jẹ́nẹ́sísì 20:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un lójú àlá pé: “Mo mọ̀ pé òótọ́ inú lo fi ṣe ohun tí o ṣe, torí ẹ̀ ni mi ò fi jẹ́ kí o dẹ́ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyẹn tí mi ò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án.
-
-
2 Kíróníkà 26:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Àmọ́, bó ṣe di alágbára tán, ìgbéraga wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi tó fi fa àjálù bá ara rẹ̀, ó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bó ṣe wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.+ 17 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àlùfáà Asaráyà àti ọgọ́rin (80) àlùfáà Jèhófà tó nígboyà wọlé tẹ̀ lé e. 18 Wọ́n kojú Ọba Ùsáyà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ùsáyà, kò tọ́ sí ọ láti sun tùràrí sí Jèhófà!+ Àwọn àlùfáà nìkan ló yẹ kó máa sun tùràrí, torí àwọn ni àtọmọdọ́mọ Áárónì,+ àwọn tí a ti yà sí mímọ́. Jáde kúrò ní ibi mímọ́, nítorí o ti hùwà àìṣòótọ́, o ò sì ní rí ògo kankan gbà lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run nítorí èyí.”
-