7 Ìbùkún ni fún ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,
Ẹni tó fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé rẹ̀.+
8 Yóò dà bí igi tí a gbìn sí etí omi,
Tó na gbòǹgbò rẹ̀ sínú odò.
Kò ní mọ̀ ọ́n lára nígbà tí ooru bá dé,
Ṣùgbọ́n àwọn ewé rẹ̀ yóò máa tutù yọ̀yọ̀ ní gbogbo ìgbà.+
Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀, kò ní ṣàníyàn,
Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní yéé so èso.