-
Diutarónómì 12:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Èyí ni àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí ẹ gbọ́dọ̀ rí i pé ẹ̀ ń pa mọ́ ní gbogbo ọjọ́ tí ẹ bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín máa fún yín pé kó di tiyín.
-
-
Diutarónómì 17:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Tó bá ti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kó fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin yìí sínú ìwé* kan, látinú èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà tọ́jú.+
19 “Ọwọ́ rẹ̀ ni kó máa wà, kó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ kó lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí àti àwọn ìlànà yìí, kí o máa pa wọ́n mọ́.+
-