9 Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe é ní jàǹbá, ṣé ẹnì kan lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà,+ kó má sì jẹ̀bi?”+ 10 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa mú un balẹ̀,+ ó sì lè kú lọ́jọ́ kan+ tàbí kó lọ sójú ogun kó sì kú síbẹ̀.+