8 Mú kí àìṣòótọ́ àti irọ́ jìnnà sí mi.+
Má ṣe fún mi ní òṣì tàbí ọrọ̀.
Ṣáà jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi,+
9 Kí n má bàa yó tán, kí n sì sẹ́ ọ, kí n sọ pé, “Ta ni Jèhófà?”+
Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n wá jalè, kí n sì kó ìtìjú bá orúkọ Ọlọ́run mi.