-
Diutarónómì 15:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+ 8 Ṣe ni kí o lawọ́ sí i,+ kí o sì rí i dájú pé o yá a ní* ohunkóhun tó bá nílò tàbí tó ń jẹ ẹ́ níyà.
-