-
Ìfihàn 21:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ni mo bá gbọ́ ohùn kan tó dún ketekete látorí ìtẹ́ náà, ó sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, á máa bá wọn gbé, wọ́n á sì jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa wà pẹ̀lú wọn.+ 4 Ó máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn,+ ikú ò ní sí mọ́,+ kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.+ Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”
-