41 Àwọn tó wà pẹ̀lú wọn ni Hémánì àti Jédútúnì+ pẹ̀lú ìyókù àwọn ọkùnrin tí a fi orúkọ yàn láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà,+ nítorí “ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé”;+
25Síwájú sí i, Dáfídì àti àwọn olórí àwùjọ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ya àwọn kan lára àwọn ọmọ Ásáfù, Hémánì àti Jédútúnì+ sọ́tọ̀ láti máa fi háàpù, àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín+ àti síńbálì*+ sọ tẹ́lẹ̀. Orúkọ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí ni,