-
Diutarónómì 16:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ.
-
-
2 Kíróníkà 30:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Lẹ́yìn náà, gbogbo ìjọ náà pinnu láti fi ọjọ́ méje míì ṣe àjọyọ̀ náà, torí náà, wọ́n fi ọjọ́ méje tó tẹ̀ lé e ṣe é tìdùnnútìdùnnú.+ 24 Hẹsikáyà ọba Júdà wá fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn ṣe ọrẹ fún ìjọ náà, àwọn ìjòyè sì fi ẹgbẹ̀rún kan (1,000) akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àgùntàn ṣe ọrẹ fún ìjọ náà;+ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì ń ya ara wọn sí mímọ́.+
-