-
Ẹ́kísódù 13:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “Ní ọjọ́ iwájú, tí ọmọ yín bá bi yín pé, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ kí ẹ sọ fún un pé, ‘Ọwọ́ agbára ni Jèhófà fi mú wa kúrò ní Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú.+
-
-
Nọ́ńbà 21:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ìdí nìyẹn tí ìwé Àwọn Ogun Jèhófà fi sọ̀rọ̀ nípa “Fáhébù tó wà ní Súfà àtàwọn àfonífojì Áánónì
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 6:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ni Gídíónì bá sọ fún un pé: “Má bínú olúwa mi, tó bá jẹ́ pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo èyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa?+ Ibo ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ wà, èyí tí àwọn bàbá wa ròyìn ẹ̀ fún wa+ pé, ‘Ṣebí Jèhófà ló kó wa kúrò ní Íjíbítì?’+ Jèhófà ti pa wá tì+ báyìí, ó sì ti fi wá lé Mídíánì lọ́wọ́.”
-