10 Ó fèsì pé: “Èmi yóò dá májẹ̀mú kan: Níṣojú gbogbo èèyàn rẹ, èmi yóò ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí wọn ò ṣe* rí ní gbogbo ayé tàbí láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè,+ gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń gbé láàárín wọn yóò rí iṣẹ́ Jèhófà, torí ohun àgbàyanu ni màá ṣe fún yín.+