10 Ó wá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ, ọmọ mi. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o fi hàn lọ́tẹ̀ yìí dáa ju ti ìgbà àkọ́kọ́ lọ,+ torí pé o ò lọ wá ọ̀dọ́kùnrin, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà. 11 Ọmọ mi, má bẹ̀rù. Gbogbo ohun tí o sọ ni màá ṣe fún ọ,+ kò kúkú sí ẹni tí kò mọ̀ ní ìlú yìí pé obìnrin àtàtà ni ọ́.