-
Òwe 21:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ẹni burúkú ni ìràpadà fún olódodo,
A ó sì mú oníbékebèke dípò adúróṣinṣin.+
-
-
Dáníẹ́lì 6:23, 24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Inú ọba dùn gan-an, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà. Nígbà tí wọ́n gbé Dáníẹ́lì jáde kúrò nínú ihò náà, kò fara pa rárá, torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.+
24 Ọba wá pàṣẹ, wọ́n mú àwọn ọkùnrin tó fẹ̀sùn* kan Dáníẹ́lì wá, wọ́n sì jù wọ́n sínú ihò kìnnìún, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àtàwọn ìyàwó wọn. Àmọ́, wọn ò tíì dé ìsàlẹ̀ ihò náà tí àwọn kìnnìún náà fi bò wọ́n, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn túútúú.+
-