-
Nehemáyà 5:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Mo sọ fún wọn pé: “A ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí wọ́n tà fún àwọn orílẹ̀-èdè pa dà débi tí agbára wa gbé e dé; àmọ́, ṣé ẹ máa wá ta àwọn arákùnrin yín ni,+ ṣé ó yẹ ká tún rà wọ́n pa dà lọ́wọ́ yín ni?” Ni kẹ́kẹ́ bá pa mọ́ wọn lẹ́nu, wọn ò sì rí nǹkan kan sọ. 9 Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe yìí kò dára. Ṣé kò yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run wa+ kí àwọn orílẹ̀-èdè, ìyẹn àwọn ọ̀tá wa má bàa pẹ̀gàn wa ni?
-