-
1 Sámúẹ́lì 25:35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Ni Dáfídì bá gba ohun tó mú wá fún un, ó sì sọ fún un pé: “Máa lọ sí ilé rẹ ní àlàáfíà. Wò ó, mo ti gbọ́ ohun tí o sọ, màá sì ṣe ohun tí o béèrè.”
-
-
Òwe 18:16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tó fúnni;+
Ó ń jẹ́ kó dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni ńlá.
-
-
Òwe 19:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá ojú rere èèyàn pàtàkì,*
Gbogbo èèyàn ló sì ń bá ẹni tó ń fúnni lẹ́bùn ṣọ̀rẹ́.
-