10 Ojoojúmọ́ ló ń bá Jósẹ́fù sọ ọ́, àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà rárá láti bá a sùn tàbí kó wà pẹ̀lú rẹ̀. 11 Lọ́jọ́ kan tí Jósẹ́fù wọnú ilé lọ ṣiṣẹ́ rẹ̀, kò sí ìránṣẹ́ ilé kankan nínú ilé. 12 Obìnrin náà di aṣọ rẹ̀ mú, ó sì sọ pé: “Wá bá mi sùn!” Àmọ́ Jósẹ́fù fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì sá jáde.