-
Ìsíkíẹ́lì 26:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 “Ọmọ èèyàn, torí pé Tírè ti sọ nípa Jerúsálẹ́mù pé,+ ‘Àháà! Wọ́n ti fọ́ ilẹ̀kùn àwọn èèyàn náà!+ Gbogbo nǹkan á di tèmi, màá sì wá di ọlọ́rọ̀ torí ó ti di ahoro báyìí’; 3 torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Màá bá ọ jà, ìwọ Tírè, màá sì gbé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè dìde sí ọ, bí òkun ṣe ń gbé ìgbì rẹ̀ dìde.
-