41 Ṣùgbọ́n Ísọ̀ di Jékọ́bù sínú torí pé bàbá rẹ̀ ti súre fún un,+ Ísọ̀ sì ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: “Ọjọ́ tí a máa ṣọ̀fọ̀ bàbá mi ti ń sún mọ́lé.+ Lẹ́yìn náà, ṣe ni màá pa Jékọ́bù àbúrò mi.”
31 Ní gbogbo ìgbà tí ọmọ Jésè bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀, ìwọ àti ipò ọba rẹ kò ní lè fìdí múlẹ̀.+ Ní báyìí, ní kí wọ́n lọ mú un wá fún mi, nítorí pé ó gbọ́dọ̀ kú.”*+
11 Torí ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa;+12 kì í ṣe bíi Kéènì, tó jẹ́ ti ẹni burúkú náà, tó sì pa àbúrò rẹ̀.+ Kí nìdí tó fi pa á? Torí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú,+ àmọ́ ti àbúrò rẹ̀ jẹ́ òdodo.+