ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 17:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ.

  • Diutarónómì 17:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Kò sì gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀, kí ọkàn rẹ̀ má bàa yí pa dà;+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ kó fàdákà àti wúrà rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀.+

  • 1 Àwọn Ọba 11:1-3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+ 2 Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. 3 Ó ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì,* ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí i lọ́kàn pa dà.*

  • Nehemáyà 13:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Ṣé kì í ṣe tìtorí èyí ni Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì fi dẹ́ṣẹ̀? Kò sí ọba tó dà bíi rẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè;+ Ọlọ́run rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ débi pé ó fi í jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ àwọn àjèjì obìnrin tó fẹ́ mú òun pàápàá dẹ́ṣẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́