Jẹ́nẹ́sísì 4:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 àmọ́ kò ṣojúure sí Kéènì rárá, kò sì gba ọrẹ rẹ̀. Torí náà, Kéènì bínú gan-an, inú rẹ̀ ò sì dùn.* Ẹ́sítà 5:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Lọ́jọ́ náà, tayọ̀tayọ̀ ni Hámánì fi jáde lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì rí Módékáì ní ẹnubodè ọba, tó sì rí i pé kò dìde, kò sì wárìrì níwájú òun, inú bí Hámánì gan-an sí Módékáì.+ Òwe 14:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Ẹni tó bá tètè ń bínú máa ń hùwà òmùgọ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò* ni aráyé ń kórìíra. Òwe 14:29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 29 Ẹni tí kì í tètè bínú ní ìjìnlẹ̀ òye,+Àmọ́ ẹni tí kò ní sùúrù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+ Òwe 29:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára* òmùgọ̀ ló máa ń sọ jáde,+Àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń mú sùúrù.+
9 Lọ́jọ́ náà, tayọ̀tayọ̀ ni Hámánì fi jáde lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì rí Módékáì ní ẹnubodè ọba, tó sì rí i pé kò dìde, kò sì wárìrì níwájú òun, inú bí Hámánì gan-an sí Módékáì.+