24 Ní báyìí, bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tí ó fìdí mi múlẹ̀ gbọn-in,+ tí ó mú mi jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá mi, tí ó sì kọ́ ilé fún mi+ bí ó ti ṣèlérí, òní ni a ó pa Ádóníjà.”+ 25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọba Sólómọ́nì rán Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà, ó jáde lọ, ó ṣá Ádóníjà balẹ̀, ó sì kú.