22 Mo sì rí i pé kò sí ohun tó dáa fún èèyàn ju pé kó gbádùn iṣẹ́ rẹ̀,+ nítorí ìyẹn ni èrè* rẹ̀; torí ta ló lè mú kó rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti lọ?+
18 Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+
9 Máa gbádùn ayé rẹ pẹ̀lú aya rẹ ọ̀wọ́n+ ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, tí Ó fún ọ lábẹ́ ọ̀run,* ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, torí ìyẹn ni ìpín rẹ nígbèésí ayé àti nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ, èyí tí ò ń fi gbogbo agbára rẹ ṣe lábẹ́ ọ̀run.+