-
Oníwàásù 3:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 nítorí pé ohun* kan wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn, ohun kan sì wà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹranko; ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ Bí ọ̀kan ṣe ń kú, bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní.+ Torí náà, èèyàn kò lọ́lá ju ẹranko lọ, nítorí pé asán ni ohun gbogbo. 20 Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ.+ Inú erùpẹ̀ ni gbogbo wọn ti wá,+ inú erùpẹ̀ sì ni gbogbo wọn ń pa dà sí.+
-
-
Oníwàásù 9:2, 3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn* gbogbo wọn,+ àti olódodo àti ẹni burúkú,+ ẹni rere pẹ̀lú ẹni tó mọ́ àti ẹni tí ò mọ́, àwọn tó ń rúbọ àti àwọn tí kì í rúbọ. Ìkan náà ni ẹni rere àti ẹlẹ́ṣẹ̀; bákan náà ni ẹni tó búra rí pẹ̀lú ẹni tó ń bẹ̀rù láti búra. 3 Ohun kan ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* tó ń kó ìdààmú báni: Nítorí ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn,+ aburú ló kún ọkàn àwọn ọmọ èèyàn; ìwà wèrè wà lọ́kàn wọn ní ọjọ́ ayé wọn, lẹ́yìn náà wọ́n á kú!*
-
-
Oníwàásù 9:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Mo tún ti rí nǹkan míì lábẹ́ ọ̀run,* pé ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́gbọ́n kì í fìgbà gbogbo rí oúnjẹ jẹ, ìgbà gbogbo kọ́ sì ni àwọn olórí pípé máa ń ní ọrọ̀,+ bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí,+ nítorí ìgbà àti èèṣì* ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.
-