Sáàmù 78:69 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 69 Ó mú kí ibi mímọ́ rẹ̀ lè máa wà títí lọ bí ọ̀run,*+Bí ayé tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+ Sáàmù 104:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Ó ti gbé ayé kalẹ̀ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀;+A kì yóò ṣí i nípò* títí láé àti láéláé.+ Sáàmù 119:90 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 90 Òtítọ́ rẹ wà láti ìran dé ìran.+ O ti fìdí ayé múlẹ̀ gbọn-in, kó lè máa wà nìṣó.+