-
2 Kíróníkà 25:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nítorí náà, Jèhófà bínú gan-an sí Amasááyà, ó sì rán wòlíì kan sí i tó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń sin àwọn ọlọ́run àwọn èèyàn tí kò gba àwọn èèyàn wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ?”+ 16 Bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ọba sọ pé: “Ṣé a fi ọ́ ṣe agbani-nímọ̀ràn ọba ni?+ Dákẹ́!+ Àbí o fẹ́ kí wọ́n pa ọ́ ni?” Àmọ́, kí wòlíì náà tó dákẹ́, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò sì fetí sí ìmọ̀ràn mi.”+
-